Ìwé Ìléwọ Atọnisọnà fún Ọsìn Adìyẹ tí ó Péye lábẹ Ìyípadà Ojú Ọjọ (Manual for Better Poultry Management Practices with Changes in Climate)
Feed the Future Innovation Lab for Food Security Policy
Nigeria Agricultural Policy Project & Alliance for African Partnership
November 2018
Orísun: Àwọn Olùkọwé
Kín ni ìyípadà ojú ọjọ?
Ìyípadà ojú ọjọ jẹ àwọn ìyípadà ọlọjọ-pípẹ tí ó jẹyọ nìnúu ètò bí ojú ọjọ ṣe máa ńrí láti ìgbà dé ìgbà. Èyí ni ó ń farahàn látàri ìwọn ooru àyíká t'ó ga, àrọọrọdá, àìṣedéédé, àti ségesège òjò, àìlèsọ bí ojú ọjọ yóò ṣe rí, àti àwọn ìṣẹlẹ t'ó ń jẹ yọ lemọlemọ. Kìí sìí ṣe gbogbo àwọn ìyípadà náà ni a kò lè ṣe àkíyèsí wọn láti ọjọ de ọjọ àti ìgbà dé ìgbà. Ṣùgbọn lẹhìn ìgbà pípẹ, àwọ
Kín ni àkóbá tí ìyípadà ojú ọjọ lè ṣe fún oko adìyẹ rẹ?
Ìyípadà ojú ọjọ máa ńfa wàhálà ooru àti àibalẹ ara púpọ fún àwọn adìyẹ. Wàhálà ooru àti àibalẹ ara yìí ń ṣẹlẹ látàrí àsìkò ooru t’ó gbóná ju bí ó ti yẹ lọ tàbí nígbà tí àwọn adìyẹ bá kojú ọjọ bíi mélo kan tí ó gbóná jọjọ. Níwọngbà t’ó jẹ wípé oúnjẹ jíjẹ adìyẹ máa ń dínkù pẹlú bí ooru bá ṣe pọ sí, wàhálà ooru ní ipa lóríi gbogbo ipele ọsìn adìyẹ: lòríi dìdàgbà, lòríi iwọn àti dídára ẹran àti ẹyin adìyẹ àti pàápàá lòríi adánidá adìyẹ láti dènà àìsàn. Ooru àyíká t’ó bá ti kọjá ìdiwọn ọgbọn (30-degrees Celcius), èyí tí ó wọpọ lásìkò yí, máa ń dín títẹwọn àwọn adìyẹ kù, á sì máa ṣokùnfa ikú ọwọọwọọ. Ó ṣeéṣe kí o ti ṣe àkíyèsí wípé tí omi mímu bá gbóná, adìyẹ kò níí mu omi, wọn kò sì níí jeun dáradára. Èyí já sí ẹdínkù iye ẹyin adìyẹ àbọyé àti títóbi adìyẹ àbọpa. Ní àfikùn, ìwọn ooru tó ga ju máa ńṣe okùnfa pípọsi àjàkalẹ àrùn. Lápapọ, ìyípadà ojú ọjọ léwu fún yíyé, pípamọ àti dídàgbà adìyẹ. Bí ìdàgbàsókè iṣẹ ọsìn adìyẹ nípa yíyé, pípamọ àti dídàgbà bá wá relẹ, èrè lóríi ọsìn adìyẹ yíò dínkù, àgbẹ yóò sì mọọ lára.
Kíwá ni o leè ṣe báyìí?
Ìròyìn ayọ! Àwọn ọnà àbùdá wà tí àgbẹ lè gbée gbà ní kíákíá láti dín ipa wàhálà ooru kù. A ti bá àwọn àgbẹ bíi tìrẹ sọrọ ní àsìkì ìdánilẹkọọ àti àbẹwò sí oko wọn. Àwọn àgbẹ wọnyí jẹ kí á mọ àwọn ọgbọn tí wọn ńta láti dín ipa tí ìṣòro ìyípadà ojú ọjọ ní lóríi ìdàgbàsóké ọsin adìyẹ wọn kù jọjọ. Ìwọ náà lè mú àwọn ọgbọn yìí lò.
Orísun: Àwọn Olùkọwé
Báwo ni o ṣe lè dín ipa ìṣòro ooru àti àìbalẹ ara kù lóríi oko ọsìn adìyẹ rẹ?
1) Yẹra fún sínsin adìyẹ aláwọ dúdú nítorí wọn máa ń gba ooru sára púpọ
2) Pèsè àyè fún atẹgún láti máa fẹẹ dáradára nínú ilé adìyẹ rẹ
3) Fún àwọn adìyẹ rẹ ní èròjà aṣara l’óore “Vitamin C” àti tọníìkì nínú omi wọn
Orísun: Àwọn Olùkọwé
4) Tí ó báá ṣeéṣe o lè wá ẹyà adìyẹ “Shika Brown” tàbí “FUNAAB Alpha” fún sínsìn nínú oko rẹ. O lè tún máa sin àwọn ẹyà adìyẹ aláwọ funfun tàbí aláwọ míràn tí ó lè fi ara da ooru
5) Àwọn ìgbésẹ láti d’ènà àìsàn ṣe pàtàkì púpọ. Tẹlé àwọn ìlànà fún abẹrẹ àjẹsára àti òògùn lílò fún àwọn adìyẹ rẹ
6) Ó dára kí á fún adìyẹ ní oúnjẹ ní bíi wákàtí mẹrin sí márùń kí ooru tó mú dé góńgó fún oúnjẹ láti dà tán n'íkùn kí ooru tó dé rárá. Èyí á jẹ kí púpọ nínúu oúnjẹ tí àwon adìyẹ náa jẹ di èròjà ara
7) Fún àwọn adìyẹ rẹ ní àwọn òògùn tí yíò dá ààbò bò wọn l'ọwọọ wàhálà ooru kí ara wọn lè mókun l'ákokò ooru
Báwo ni o se lè pèsè àyiíká tí ó silé àti omi tí ó tutù fún adìyẹ rẹ nígbà tií ooru bá ń mú?
1) Gbin àwọn igi tàbí irè bíi ọgẹdẹ láti pèsè ibòji fún àwọn adìyẹ rẹ
2) Máa pàrọ “litter” déédé láti d’ènà àkójọpọ àwọn afẹfẹẹ gáàsì tí kò dára nínú ilé adìyẹ
3) Máa ṣe àkíyèsì àwọn adìyẹ rẹ láti lè mọ iye tí o lè kó sínú ilé kan láì ṣe ìdíwọ fún lílọ bíbọ wọn àti jíjágeere atẹgùn. Èyí jásí wípé o lè nílò láti dín iye adìyẹ tí ó yẹ kí ó wà nínú ìdiwọn àyè ilé kan tàbí nínú àgò kan kù
4) Lo àwọn iná ìgbàlódé tí kìí gbagbára púpọ tí kìí sì móoru jù
5) Ri àwọn ọpá tí ó gbé omi wọlé adìyẹ mọlẹ kí omi lè máa tutù
6) Ń’jẹ ìwọ ń gb’èrò láti ní odò ẹja? Ó dára, nítorí ó lè ràn ọ lọwọ láti lè máa rí omi tútù tí o bá dá odò ẹja sóríí ilẹ kan nàá pẹlú oko adìyẹ
7) Wọn ìrì omi fẹẹrẹfẹ sí àwọn adìyẹ rẹ lára láti jẹ kí ará tù wọn nígbà tí ooru bá pọ lápọjù
8) Tí o bá ń lo àgbá omi ìgbàlódé láti tọjúu omi, o lè máa da omi tí ó bá ti gbóná nù kí o sì fa omi tuntun tí ó tutù sínúu rẹ láti inúu kànga d’ẹrọ ní gẹlẹ tí o bá fẹ fún àwọn adìyẹ rẹ ní omi. Tí ó bá sì jẹ kànga ni ò ńlò láìsí àgbá omi, o lè máa faa omi t’ó tutù t’ó sì tòrò ní gbogbo ìgbà tí o bá fẹ fún àwọn adìyẹ rẹ ní omi. Èyí yíò jẹ kí àwọn adìyẹ wọnyí máa gbádùn omi tútù tí ó dara, wọn yíò sì jẹun dáradára
9) O lè gbé àwọn àgbá omi sínú ilé adìyẹ láti d’ènà ìtànsán òòrùn tí ó lè mú kí omi gbóná lójú ọsán
10) Bí omi bá wá gbóná síbẹ síbẹ, ju yìnyín sínúu rẹ kí ó lè silé
Àwọn ńkan míràn wo ni o ní láti fi s'ọkàn fún ojọ iwájú?
1) Ní àfikún sí gbogbo àwọn ìlànà ìṣàkóso olówó táṣẹrẹ tí ó rọrùn tí a tí la sílẹ, ìwọ pàápàá lè bẹrẹ síí ṣe ètò sílẹ fún ọjọ iwájú. Àwọn onímọ ìjìnlẹ “science” ti sọ àsọtẹlẹ pé ó ṣeé ṣe kí ipa ìyípadà ojú ọjọ yí ó le síi ní agbègbe waa bí àwọn olùdarí l'ágbàáyé kò bá f'ẹnu kò l'óríi ọnà àbáyọ làti d’ènà àwọn ńkan wọnyí
2) Bí o bá ń gb'èrò láti kọ ilé adìyẹ titun, o nílò láti fi àwọn kókó kan sọkàn nípa bí ilé náà yíò ṣe dúró. Oòrùn ńyọ láti ìlà-oòrùn ó sì ńwọ sí ìwọ oòrùn. Látàri bẹẹ, ẹgbẹ ibi tí ó gùn jù nínú ilé adìyẹ gbọdọ d'ojú kọ àríwá àti gúsù. Nípa bẹẹ ìtànsán oòrùn tíi yíò wo inú ilé adìye náà yíò dínkù, ilé adìyẹ bẹẹ yíò sì máa silé
3) Ríi dájú pé àjà ilé adìyẹ náà ga dáradára, kí ògiri tí o mọ sí ìsàlẹẹ rẹ má sì ga rárá fún atẹgùn láti lè fẹ yíká dáradára nínú ilé adìyẹ
4) Máa lo ìgbà àti bí ooru ṣe mú sí láti díwọn iye adìyẹ tí oóò kó s'ínú ilé kan Bí ó bá ṣe ìgbèríko ni oko rẹ wa, kàkà kí o fi símẹntì mọ odi yíi ká, o lè fi wáyà onírin ṣe ọgbà. Èyí yíò dáàbò bo oko rẹ, yíò sì tún jẹ kí atẹgùn fẹ dáradára ju ti odi oní símẹntì tàbí búlọọkù. Ó dára láti lo abala “aluminium” tàbi “asbestos” láti ṣe òrùlé ilé adìye ju ti “Zinc” lọ, nítorípé “Zinc” máa ń fa ooru sínú ilé adìyẹ. Fún àwọn ilé adìyẹ tí o ti kọ tẹlẹ, o lè fi ẹrọ af’átẹgùn s’ínúu wọn kí atẹgùn lé fẹdáradára fún àwọn adìyẹ.
Orísun: Àwọn Olùkọwé
Fún àmọràn síwájú síi tàbí ẹkúnrẹrẹ àlàyé l’órí ìwé ìléwọ yìí, kàn sí: Dr. Kazeem Bello (Federal University of Agriculture Abeokuta) kazeembello19@gmail.com +2348032204658; Dr. Buba Wahe (NAERLS, Ahmadu Bello University, Zaria, bubawahe@gmail.com +234806539885), Dr. Toba Adeyeye (+2348083058853) tàbi Dr. Saweda Onipede Liverpool-Tasie (Michigan State University,lliverp@msu.edu). Ttranslated by Dr. Olalekan Oyekunle, Media and Farm Broadcast (MFB), AMREC, Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB) and Mr. Idris Taiwo Olabode - MFB, AMREC, FUNNAB,
Ìwé ìléwọ yìí ni a tẹ jàde làti ọwọọ àkójọpọ àwọn ènìyàn àgbáyé kan tí wọn ní ìtara nípa ọrọ ìyípadà ojú ọjọ àti bí oúnjẹ tí ó péye yíò ṣe pọ yanturu l’órílẹ ède Nàìjíríà (Nigeria) pẹlú ìrànlọwọ láti ọwọ àjọ Feed the Future Nigeria Agricultural Policy Project àti Michiga
Comments
Post a Comment